Eksodu 30:1-5
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Pẹpẹ tùràrí
30 (A)“Ìwọ yóò sì ṣe pẹpẹ igi kasia kan; máa jó tùràrí lórí rẹ̀. 2 Kí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé, kí ó jẹ́ ìdajì mítà ní gígùn, ìdajì mítà ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga rẹ̀—kí ìwo rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. 3 Ìwọ yóò sì bo òkè rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀ pẹ̀lú u kìkì wúrà, ìwọ yóò sì ṣe wúrà gbà á yíká. 4 Ìwọ yóò sì ṣe òrùka wúrà méjì fún pẹpẹ náà níṣàlẹ̀ ìgbátí méjèèjì ní òdìkejì ìhà rẹ̀—láti gbá àwọn òpó rẹ̀ mú, láti lè máa fi gbé e. 5 Ìwọ yóò sì ṣe òpó igi kasia, ìwọ yóò sì bọ́ wọ́n pẹ̀lú wúrà.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.